| |
Capítulo 1 Introdução
|
| |
| Ọna ti oyun inu ọmọ enia
ti o ni ẹyin kekere kanlolo
ngba ti agbalagba enia
ti o ni ẹgbẹrun lọna aadọjọ ẹyin keekeke jẹ
ifarahan ti o yanilẹnu julọ
ninu ohun gbogbo ti o wa laye.
|
| Awon oluwadi ti mọ bayi wipe, pupọ
ninu awæn isẹ ojoojumọ
ti ara agbalagba enia nse
ni a ti filelẹ lati inu oyun wa –
nigba pupọ, ki a to bi ni s’aye.
|
| Akoko idagbasoke ki ọmọ to o w’aye
ni o tubọ nye ni sii gẹgẹbi akoko ipalẹmọ,
ninu eyiti ọmọ enia ti o sẹsẹ ndagbasoke
njẹ ere orisirisi awọn ẹya-ara,
ti o si nfi orisirisi ọgbọn han,
eyiti yio lo
fun wiwa laaye lẹhin ti a ba bii tan.
|
Capítulo 2 Terminologia
|
| Oyun lara ọmọ enia
ma ngba to ọsẹ mejidinlogoji
ti a ba kaa lati igbati idapọ ba ti w’aye
laarin ẹyin ọkunrin ati obirin,
tabi lati igbati enia loyun,
titi di asiko ibimọ.
|
| Ni ọsẹ mẹjọ ekini lẹhin
idapọ ẹyin ọkunrin ati obirin,
ọmọ enia ti i ndagbasoke ninu
ni a npe ni ẹmubirayoo,
eyiti o tumọ si “idagbasoke ninu."
Akoko yi, ti a npe ni akoko ẹmubirayoo,
ma nfarahan nipa fifi
awọn orisirisi ẹya-ara le lẹ.
|
| Lati igbati ọsẹ mẹjọ ba kọja,
titi di opin iloyun,
"ọmọ enia ti ndagbasoke
ninu yi ni a npe ni fitọọsi,”
itumọ eyiti nse "ọmọ ti a ko i tii bi."
Ni akoko yi, eyiti a npe ni akoko fitọọsi,
gbogbo ẹya-ara ọmọ naa yio
dagbasoke sii, wọn yio si maa sisẹ.
|
| Gbogbo awọn akoko iloyun
ti o wa ninu eto yi
ntọka si akoko ti o bẹrẹ lati igbati
idapọ ẹyin ọkọ ati aya ti w’aye.
|