| |
O Período Fetal (8 semanas até o Nascimento)
Capítulo 37 9 Semanas: Engole, Suspira e se Estica
|
| |
| Akoko fitọsi yi wa titi di
igbati a o bi ọmọ naa.
|
| Ni ọsẹ kẹsan,
ọmọ inu oyun naa yio bẹrẹ sii mu ika rẹ,
o si le gbe omi inu apo ile-ọmọ mi.
|
| Ọmọ inu oyun naa le di nkan mu,
o le mi ori rẹ siwaju ati sẹhin,
o le la ẹnu rẹ, o le gbe ahọn rẹ,
o le poS̩e, osi le na.
Isan-ara ti o wa ni oju, atẹlẹwọ,
ati atẹlẹsẹ ma nmọ ọ lara
bi a ba fi ọwọ kan wọn.
“Bi a ba rọra fi ọwọ kan gigise,”
ọmọ inu oyun yio rọ ibadi rẹ ati
orunkun rẹ yio si lẹ ọmọ-ika ẹsẹ rẹ pọ
|
| Ipenpeju ọmọ naa
yio bo oju rẹ patapata.
|
| Ninu apoti ifọhun ti o wa ni ọna-ọfun,
ifarahan awọn edidi
ni yio fihan wipe awọn okun
ti a fi nfọhun ti ndagbasoke.
|
| Ni ara ọmọ inu oyun ti o jẹ obirin,
a ti le da apo ile-ọmọ mọ,
awọn ẹyin ile-ọmọ ti ko i tii dagba tan,
ti a npe ni hugonia
wa ninu apo ile-ọmọ naa,
nibiti wọn ti npin si ọna pupọ.
Awọn ẹya ara ti o wa fun
ọmọ bibi yio ma farahan
gẹgẹbi ẹya ara ọkunrin tabi ti obirin.
|
Capítulo 38 10 Semanas: Revira os olhos e Boceja, Unhas e Impressões Digitais
|
| |
| Orisirisi awọn idagbasoke ti nwaye
laarin ọsẹ kẹsan si ikẹwa
yio mu ki ara ọmọ naa o tobi sii
bi iwọn marundinlọgọrin ninu ọgọrun.
|
| Ni ọsẹ kẹwa,
bi a ba fọwọkan ipenpeju ọmọ naa,
yio yi ẹyin-oju rẹ si isalẹ.
Ọmọ inu oyun naa le yan,
o le la ẹnu rẹ, ki o si paade.
|
| Ọpọlọpọ ọmọ inu oyun
ni maa nmu atanpako wọn ọtun.
Apa kan lara ifun,
nibiti ibi-ọmọ wa
yio ma wọnu ara pada si inu ikun.
|
| Awọn egungun yio maa le sii.
|
| Eekanna ọwọ ati ti ẹsẹ
yio bẹrẹ sii hu jade.
|
| Aami ori ika-ọwọ yio bẹrẹ sii han ni
ọsẹ kẹwa lẹhin idapọ ọkunrin ati obirin.
Aami yi ni a fi nda enia mọ
ni gbigbo ọjọ aye rẹ.
|
Capítulo 39 11 Semanas: Absorve Glicose e Água
|
| |
| Ni ọsẹ kọkanla,
imu ati ete
ti yọ jade daradara.
Gẹgẹbi oS̩e wa ni awọn ẹya ara yoku,
irisi wọn yio ma yipada
lati igba de igba,
ninu igbesi-aye ọmọ enia naa.
|
| Ifun inu yio bẹrẹ sii fa S̩uga ati omi
ti ọmọ inu oyun naa ba gbemi mu.
|
| Biotilẹjẹpe ẹya akọ tabi abo ma nfarahan
lati igbati idapọ ẹyin
ọkọ ati aya ba ti waye,
awọn ẹya ara ti o wa fun ọmọ bibi
ni a le damọ bayi,
gẹgẹ bi ẹya ti akọ tabi ti abo.
|