| |
Capítulo 40 3 a 4 Meses (12 a 16 Semanas): Papilas Gustativas, Movimento de Mandíbula, Reflexo de Sucção, Percepção dos Primeiros Movimentos do Feto
|
| |
| Laarin ọsẹ kọkanla si ikejila,
iwọn ara ọmọ inu oyun naa
yio pọ sii pẹlu iwọn ọgọta ninu ọgọrun.
Ọsẹ kejila ni opin ipele akọkọ ninu mẹta,
igba ti obirin fi nloyun.
|
| Awọn ohun ti a fi nse itọwo ounjẹ
yio bo gbogbo ayika ẹnu.
|
| Bi a ba bimọ naa tan,
awọn ohun itọwo wọnyi yioS̩i wa nipo
lori ahọn nikan, ati ni oke ẹnu.
|
| Igbẹ yiya yio bẹrẹ lati bi ọsẹ kejila,
yio si tẹsiwaju fun bi ọsẹ mẹfa sii.
Ohun akọkọ tii ma jade lati
idi ọmọ inu oyun ati ọmọ ti a S̩ẹS̩ẹ bi
ni a npe ni mẹkoniọmu.
Ninu rẹ ni a ti le ri
awọn ohun ti nmu ounjẹ da,
ounjẹ tii mu ni dagbasoke,
ati awọn ẹyin keekeke ti ko wulo mọ,
eyiti o jade lati inu
ẹya ara ti ngbe ounjẹ kaakiri ara.
|
| Ni ọsẹ kejila, gigun ọwọ
ti fẹrẹ to iwọn ti o yẹ fun ara.
Ẹsẹ ma npọ diẹ sii
ki o to gun to bi o ti yẹ fun ara.
|
| Bi a ba yọ ti ẹhin ati oke ori kuro,
gbogbo ara ọmọ inu oyun naa ni o ma
nfesi, bi a ba rọra fọwọ kan wọn.
|
| Awọn idagbasoke
ti o ba ti ẹya akọ tabi abo lọ
yio farahan fun igba akọkọ.
Fun apẹẹrẹ,
ọmọ obirin ma njẹ ẹnu rẹ bakan
ju ọmọ ọkunrin lọ.
|
| Yatọ si bi o ti ma nS̩e tẹlẹ ri,
bi a ba fọwọkan ẹnu ọmọ inu oyun yi,
yio yirapada si ọkankan ibiti
a ti fọwọkan-an, yio si la ẹnu rẹ.
Iru ifesi bayi ni a npe ni
“rutini rifulẹkisi”
o si ma ntẹsiwaju
lẹhin ti ọmọ naa ba d’aye tan,
ninu eyiti i ma ran ọmọ lọwọ
lati wa ibiti ori-ọmu iya rẹ wa,
nigbati o ba fẹ mu ọmu.
|
| Oju yio maa dagbasoke sii,
bi ọra ti nkun gbogbo ẹrẹkẹ,
bẹẹ si ni ehin naa
yio bẹrẹ sii dagbasoke.
|
| Ni ọsẹ kẹẹdogun, awọn ohun tii ma
ndi ẹjẹ lara enia yio farahan,
wọn a si maa pọ sii
ninu ọra inu egungun.
Ibiyi ni a o ti sẹda
pupọ ninu ẹjẹ ara ọmọ enia.
|
| Biotilẹjẹpe ọmọ inu oyun ti le gbe ara rẹ
lati ọsẹ kẹfa lẹhin ti a loyun rẹ,
aboyun ma nmọ, fun igba akọkọ,
wipe ọmọ inu oun ngberasọ,
laarin ọsẹ kẹrinla si ikejidinloogun.
Ninu asa abinibi,
a npe eleyi ni gbigberasọ.
|