| |
Capítulo 41 4 a 5 Meses (16 a 20 Semanas): Resposta ao Estresse, Verniz Caseoso, Ritmos Circadianos
|
| |
| Ni ọsẹ kẹrindinloogun,
ọna kan ti a ngba ki
abẹrẹ sinu ikun ọmọ inu oyun
ma nmu
ifesi kan waye,
eyiti nfa ohun kan
ti a npe ni noradirẹnalini,
tabi norẹpinẹpirini wọ inu ẹjẹ.
Ọmọ ti a S̩ẹS̩ẹ bi
ati agbalagba paapa ma nse bayi
nigbati ohun ajeji kan
ba fẹ wọnu ara wọn.
|
| Ninu ẹya ara ti a fi nmi,
ọna ti atẹgun ngba
wọnu ara ti dagbasoke daradara.
|
| Ohun kan funfun,
ti o wa fun aabo,
eyiti a npe ni famisi kasehosa,
yio bo gbogbo ara ọmọ inu oyun naa.
Famisi yi ma ndaabobo awọ-ara
kuro lọwọ awọn ohun ti npanilara,
eyiti o wa ninu omira
ti o wa ni apo ile-ọmọ.
|
| Lati ọsẹ kẹsan,
gbigbe ara, mimi atẹgun sinu,
ati lilu ọkan yio bẹrẹ sii waye
ni ojoojumọ,
ilana eyiti a npe ni
lilu ti sakediani.
|
Capítulo 42 6 a 7 Meses (24 a 28 Semanas): Reflexo Cócleo-Palpebral e de Sobressalto; Pupilas Respondem à Luz; Olfato e Paladar
|
| |
| Ni ogun ọsẹ, apa kan ninu iho eti,
eyiti o jẹ ẹya ara ti igbọran,
yio ti tobi to ti agbalagba
ninu
iho eti ti o ti dagbasoke tan naa.
Lati igba yi lọ,
ọmọ inu oyun yio maa fesi
si oriS̩iriS̩i ariwo.
|
| Irun yio bẹrẹ sii hu lori.
Gbogbo awọ-ara
ati ẹya wọn ti wa nipo,
pẹlu iho irun ati awọn
apo keekeke ti ngbe abẹ awọ-ara.
|
| Ni ọsẹ kọkanleloogun
si ikejileloogun lẹhin idapọ,
ẹdọforo yio lagbara
lati maa mi atẹgun sinu.
Ọmọ inu oyun le gbe ile-aye nisinsinyi,
nitori pe wiwa laaye
ni ode apo ile-ọmọ
yio S̩ee S̩e fun
awọn ọmọ inu oyun kan.
OriS̩iriS̩i awọn aseyọri
ninu ẹkọ ilera
njẹki o S̩ee S̩e lati mu ẹmi
awọn ọmọ ti osu wọn ko pe duro.
|