| |
Capítulo 43 5 a 6 Meses (20 a 24 Semanas): Responde ao Som; Cabelo e Pele; Idade de Viabilidade
|
| |
| Ni ọsẹ kẹrinleloogun,
ipenpeju yio S̩i soke,
oyun inu naa yio si S̩ẹju ni iyalẹnu.
Iru ifesi bayi
si ariwo ti a pa lojiji
ti ma nwaye ni kiakia ju bayi lọ
lara ọmọ inu oyun ti o jẹ obirin.
|
| Awọn oluwadi fi ye wa wipe
ariwo ti o pọ ju
le S̩e jamba fun ilera ọmọ inu oyun.
Awọn ijamba tii ma ntete waiye
ni ki ọkan maa mi titi
laini idaduro,
ki ọmọ inu oyun maa gbe itọ mi ju
bi o ti yẹ lọ, ati awọn iwa ojiji miran.
Awọn jamba ti maa waye lọjọ pipẹ
lẹhin eyi ni ailegbọran daada.
|
| Iwọn bi ọmọ inu oyun se nmi
le lọ soke
to fifa atẹgun simu
lẹẹmẹrinlelogoji laarin iS̩ẹju kan.
|
| Ni asiko ti o jẹ ipele kẹta
ninu igba ti obirin fi nloyun,
idagbasoke ọpọlọ ma nlo to idaji
ninu gbogbo okun inu
ti ọmọ inu oyun nlo.
Ọpọlọ yio tobi sii ni iwọn ti o to
ilọpo mẹrin si marun.
|
| Ni ọsẹ kẹrindinlọgbọn,
oju yio yọ omije.
Ẹyin oju ma nfesi si imọlẹ
lati bi ọsẹ kẹtadinlọgọn.
Ifesi yi ma nse ilana
bi imọlẹ ti ntan
sinu ẹyin oju,
ni gbogbo ọjọ ti ọmọ naa yio gbe laye.
|
| Ohun gbogbo ti o wulo
fun gbigb’oorun nkan
ti bẹrẹ sii S̩iS̩ẹ.
Ẹkọ lori awọn ọmọ
ti osu wọn ko pe
S̩e akiyesi agbara ati gbọ oorun
lati bi ọsẹ kẹrindinlọgbọn
lẹhin idapọ ẹyin.
Bi a ba fi ohun ti o ladun sinu
omira apo ile-ọmọ,
ọmọ naa yio ma gbe itọ mi
ju bi o ti yẹ lọ.
Sugbọn ọmọ inu oyun kii gbe
itọ mi to bi o ti yẹ
bi a ba fi ohun ti o koro
sinu omira.
Ọmọ naa yio fun oju rẹ pọ lẹhin naa.
|
| Nipasẹ oriS̩iriS̩i awọn igbesẹ
bi ti enia ti nrin,
ọmọ inu oyun naa ma ntakiti ọbọ.
|
| Ara ọmọ inu oyun naa
ki yio wunjọ bii ti atẹhinwa
bi ọra S̩e nkun abẹ awọ-ara rẹ.
Ọra nS̩e iS̩ẹ pataki ni mimu
iwọn otutu tabi ooru ara enia duro,
ati ni pipese okun-inu lẹhin ibimọ.
|
Capítulo 44 7 a 8 Meses (28 a 32 Semanas): Discriminação de Sons, Estados Comportamentais
|
| |
| Ni ọsẹ kejidinlọgbọn,
ọmọ inu oyun le mọ iyatọ
laarin bi nkan S̩e ndun si ni leti.
|
| Ni ọgbọn ọsẹ,
fifa atẹgun s’imu wọ pọ,
o si ma nwaye ni iwọn ọgbọn si ogoji
ninu ọgọrun igba, lara ọmọ inu oyun.
|
| Ni oS̩u mẹrin ti o kẹhin ninu oyun,
ọmọ inu oyun ma nhu
awọn iwa kan letoleto,
laarin eyiti o ma nni akoko isinmi.
Awọn iwa wọnyi
nfihan bi isẹ ti
ọpọlọ ati awọn ka rẹ nS̩e ti lagbara to.
|
Capítulo 45 Os Membros e a Pele
|
| |
| Nigbati o ba to ọsẹ mejilelọgbọn,
awọn iho,
tabi apo atẹgun,
yio bẹrẹ sii waye ninu ẹdọforo.
Wọn yio maa dagba sii titi di
igba ti ọmọ naa yio pe ọmọ ọdun mẹjọ.
|
| Ni ọsẹ karundinlogoji,
ọmọ inu oyun le di nkan mu giri.
|
| Ohun ti o wa ni
ayika ibiti oyun inu ti dagba
ma ntọka si awọn ohun ti yio fẹran
lati maa jẹ lẹhin ti a ba bii.
Fun apẹẹrẹ, ọmọ inu oyun ti iya rẹ jẹ
ohun ti a npe ni aniisi,
eyiti o fun ounjẹ kan
ti a npe ni likorisi ni adun rẹ,
fẹran lati maa jẹ aniisi naa
lẹhin ti a bii tan.
Ọmọ ikoko ti iya rẹ ko ni ohun kan se
pẹlu aniisi ko fẹran ounjẹ naa rara.
|
Capítulo 46 9 Meses até o Nascimento (36 Semanas até o Nascimento)
|
| |
| Ọmọ inu oyun yio mu ki irọbi bẹrẹ
nigbati ohun kan ti a npe ni
ẹsitirogini ba njade lara rẹ,
ti o si bẹrẹ ayipada rẹ
lati ọmọ inu oyun si ọmọ ikoko.
Rirọbi ma nwaye pẹlu sisunki ile-ọmọ,
eyiti yio fa bibi ọmọ.
|
| Lati akoko idapọ ẹyin
titi di igba ibimọ ati siwaju sii,
idagbasoke ọmọ enia ta yọ, o wa titi aye,
o si jẹ ohun ti o diju lọpọlọpọ.
Imọ ẹkọ titun nipa
ilana ti o fanimọra yi
nfi anfaani ti o wa ninu idagbasoke oyun
lori ilera ọmọ enia ni gbogbo
igbesiaye rẹ han.
Bi imọ wa nipa idagbasoke
ọmọ ninu oyun ti ntẹsiwaju,
bẹẹni anfaani ti a ni lati jẹki ilera
ọmọ enia tubọ fẹsẹmulẹ ngbooro sii-
ki a to bimọ, ati bi a ba bii tan.
|