| |
Desenvolvimento Embrionário: 4 a 6 Semanas
Capítulo 11 4 Semanas: Líquido Amniótico
|
| |
| Ni ọsẹ kẹrin,
omi-ara ti o mọ tonitoni yi
yio san yika ọmọ inu oyun
ninu apo ile ọmọ.
Omi ti ko ni abawọn yi,
ti a npe ni omira,
ma ndaabobo oyun inu lọwọ ipalara.
|
Capítulo 12 O Coração em Ação
|
| |
| Ọkan enia ma nmi niwọn igba
mẹtalelaadọfa laarin isẹju kan.
Sakiyesi bi awọ ara ọkan naa ti nyipada
bi ẹjẹ ti nwọ inu awọn iho rẹ,
ti o si njade.
Ọkan enia maa nmi niwọn igba
mẹrinlelaadọta miliọnu ki a to bi ni,
ati niwọn igba miliọnu mẹta, o le diẹ
ni igbesi aye enia
ti o pe ọmọ ọgọrin ọdun.
|
Capítulo 13 O Crescimento do Cérebro
|
| |
| Idagbasoke ọpọlọ ma nfi ara han
nipa bi iyatọ se nwa ninu irisi
ọpọlọ iwaju,
ọpọlọ aarin,
ati ọpọlọ ẹhin.
|
Capítulo 14 Brotos dos Membros
|
| |
| Ọwọ ati ẹsẹ yio bẹrẹ sii yọ jade
nigbati idi wọn ba farahan ni ọsẹ kẹrin.
|
| Awọ ara ọmọ inu oyun naa ni asiko yi
yio mọ gaara
nitori pe ko nipọn pupọ.
Bi awọ ara naa se nnipọn sii,
ni mimọ ti o mọ yio maa dinku,
eyiti o tumọ si wipe
a le maa wo bi awọn ẹya inu ara
ti ndagba, fun osu kan sii.
|
Capítulo 15 5 Semanas: Hemisférios Cerebrais
|
| |
| Laarin ọsẹ kẹrin si ikarun,
ọpọlọ yio maa dagbasoke ni kiakia sii,
yio si pin si ọna marun ọtọọtọ.
Ori jẹ iwọn kan ninu idamẹta
gbogbo ara ọmọ inu oyun naa.
Ọpọlọ iwaju
yio gba aaye ti o pọ fun ara rẹ,
yio si di ẹya ti o tobi ju ninu ọpọlọ.
Awọn iS̩ẹ ti ọpọlọ iwaju yi wa fun
ni ironu, ẹkọ kikọ,
iranti nkan, ọrọ sisọ, iriran,
igbọran, gbigbe ọwọ tabi ẹsẹ,
ati yiyanju ọran ti o S̩oro.
|
Capítulo 16 Vias Respiratórias Principais
|
| |
| Ninu ẹya ara ti ngbe atẹgun kaakiri ara,
iho ti atẹgun ngba pin si ọna meji,
ni apa ọtun ati apa osi,
eyi si ni yio so
ọna ọfun
pọ mọ ẹdọforo.
|
Capítulo 17 Fígado e Rins
|
| |
| Sakiyesi ẹdọ nla
ti o gba aaye ti o pọ ninu ikun,
ni abẹ ọkan ti nmi naa.
Kidirin ti yio wa titi aye
yio farahan ni ọsẹ karun.
|
Capítulo 18 Saco Vitelino e Células Germinativas
|
| |
| Ninu apo ẹyin
ni awọn yin keekeke fun ọmọ bibi,
eyiti a npe ni jamu sẹẹli, wa.
Ni ọsẹ karun,
awọn ẹyin keekeke wọnyi yio lọ
si ẹya ara ti o wa fun ọmọ bibi,
eyiti o wa l’ẹgbẹ kidinrin.
|
Capítulo 19 Placas da Mão e Cartilagem
|
| |
| Bakanna, ni ọsẹ karun,
atẹlẹwọ ọmọ inu oyun naa
yio bẹrẹ sii farahan,
kerekere yio si bẹrẹ si ni farahan
lati ọS̩u karun ati aabọ.
Ni bayi, a o S̩akiyesi atẹlẹwọ ti ọwọ osi
ati ti ọrun ọwọ,
ni ọsẹ karun ati ọjọ mẹfa.
|