| |
Desenvolvimento Embrionário: 6 a 8 Semanas
Capítulo 20 6 Semanas: Movimento e Sensação
|
| |
| Ni ọsẹ kẹfa, aaye ti ọpọlọ iwaju gba
yio maa tobi sii
ni ọna ti o ya ju
awọn ẹya ọpọlọ yoku lọ.
Ọmọ inu oyun naa yio bẹrẹ sii ni
yi sihin sọhun.
Iru yiyi sihin sọhun yi S̩e pataki
lati mu ilọsiwaju ba idagbasoke iS̩an ara.
|
| Bi a ba f’ọwọ kan ẹnu rẹ,
ọmọ inu oyun naa
yio fa ori rẹ mọra lọgan.
|
Capítulo 21 A Orelha Externa e a Formação de Célula Sanguínea
|
| |
| Eti naa ti nhu jade.
|
| Ni ọsẹ kẹfa,
ẹjẹ yio ti maa kojọpọ ninu ẹdọ,
ninu ibiti awọn ohun kan
ti ma ndaabobo ara lọwọ arun wa.
Awọn ohun ti ndaabobo ara wọnyi
jẹ koko lara apapọ awọn ẹya ara
tii ma ba arun ja lara enia.
|
Capítulo 22 O Diafragma e os Intestinos
|
| Ẹran ara
ti o wa ni agbedemeji aya ati ikun,
eyiti o jẹ ẹran ara ti enia fi nmi,
yio ti farahan ni ọsẹ kẹfa.
|
| Apa kan lara ikun
yio wu jade fun igba diẹ
sinu okun ibi-ọmọ.
Ilana yi, eyiti i ma S̩ẹlẹ nigbagbogbo,
ni a npe ni ifun yiyọjade ni ara enia.
eyi a si maa fi aaye silẹ
fun awọn ẹya ara miran ninu ikun.
|
Capítulo 23 Placas da Mão e Ondas Cerebrais
|
| |
| Ni ọsẹ kẹfa, atẹlẹwọ yio di pẹrẹsẹ.
|
| Ọpọlọ yio ti lagbara lati ronu
lati bi ọsẹ karun ati ọjọ meji.
|
Capítulo 24 Formação do Mamilo
|
| |
| Awọn sonso ori ọmu yio yọ si aya,
lẹhin eyiti wọn yio lọ si
ibiti o yẹ ki wọn o duro si
ni ookan-aya.
|
Capítulo 25 Desenvolvimento dos Membros
|
| |
| Ni ọsẹ kẹfa ati aabọ,
awọn igunpa ọwọ yio ti yanju,
aami ori ika ọwọ yio ti maa han,
enia si le maa wo ọwọ naa bi o ti nmi.
|
| Dida egungun ara,
eyiti a npe ni osifikesan
yio bẹrẹ lati ibi egungun ejika,
eyiti a npe ni egungun kọla,
ati egungun oke ati isalẹ agbọn ẹnu.
|
Capítulo 26 7 Semanas: Soluços e Resposta a Susto
|
| |
| A o ti sakiyesi wipe ọmọ inu oyun
nse osuke, ki o too to ọsẹ keje.
A le S̩akiyesi bi ọmọ inu oyun ti ngbe ẹsẹ rẹ,
nigbakugba ti ohun kan ba dẹru baa.
|
Capítulo 27 O Coração Desenvolvido
|
| |
| Ọkan ọmọ naa, eyiti o pin si ọna mẹrin,
yio ti dagbasoke tan.
Ọkan naa yio maa mi ni iwọn igba ti o to
ẹẹmẹtadinlaadọsan laarin isẹju kan.
Agbara ti ọkan ọmọ naa ni,
eyiti a se akiyesi rẹ ni ọsẹ meje aabọ,
fihan wipe eyi fẹrẹ ba ti agbalagba enia dọgba.
|
Capítulo 28 Ovários e Olhos
|
| |
| Bi o ba jẹ obirin,
a le da apo ẹyin rẹ mọ lati ọsẹ keje.
|
| Ni ọsẹ meje ati aabọ,
ohun ti a npe ni rẹtina ninu oju
ni a le se akiyesi rẹ yekeyeke,
awọn ipenpeju naa
si ti bẹrẹ sii ni tobi sii.
|
Capítulo 29 Dedos das Mãos e dos Pés
|
| |
| Awọn ika ọwọ wa lọtọ,
awọn ọmọ-ika ẹsẹ si so pọ ni isalẹ.
|
| Ọwọ ti S̩ee papọ soju kan,
bẹẹ naa si ni ẹsẹ.
Orunkun naa ti wa nipo.
|