| |
Um Embrião de 8 Semanas
Capítulo 30 8 Semanas: Desenvolvimento do Cérebro
|
| |
| Ni ọsẹ kẹjọ, ọpọlọ ti dagbasoke daada,
o si jẹ iwọn idaji ninu gbogbo ara.
Idagbasoke yio maa tẹsiwaju
ni kiakia.
|
Capítulo 31 Característica de Destro e Canhoto
|
| |
| Ni ọsẹ kẹjọ, iwọn ida marundinlọgọrin ninu
ọgọrun ọmọ inu oyun ni maa lo ọwọ ọtun.
Awọn yoku ni a le pin si
awọn ti yio lo ọwọ osi, ati awọn ti yio lo mejeeji.
Eyi ni o kọkọ fi
iwa lilo ọwọ ọtun tabi ọwọ osi han.
|
Capítulo 32 Virar
|
| |
| Iwe ẹkọ nipa ilera awọn ọmọde
se apejuwe “yiyirapada ọmọde”
gẹgẹbi iS̩ẹlẹ tii maa waye
laarin ọsẹ kẹwa si ogun ọsẹ lẹhin ibimọ.
sugbọn iru iwa ti o yanilẹnu yi
ma nsaba waye nibiti
agbara ti nfa ohun gbogbo walẹ ko ti pọ,
ninu apo ile-ọmọ,
eyiti omi kun inu rẹ.
Aini agbara ti o pọ to
lati bori agbara ti nfa ohun gbogbo walẹ yi
ni ayika ti o yatọ si ti ile-ọmọ, ni ko le
jẹki ọmọ ti a sẹsẹ bi le yi ara rẹ pada.
|
| Ọmọ inu oyun naa ti le se ohun pupọ
ni akoko yi.
O le maa yi sihin sọhun
pẹlu ilọra tabi irọrun,
lẹẹkọkan tabi leralera,
lati inu wa tabi lairotẹlẹ.
Yiyi ori, nina ọrun, ati kika ọwọ ko sibi ori
ma nwaye ni igba pupọ.
|
| Bi a ba fọwọ kan-an,
ọmọ inu oyun naa yio yara di oju rẹ,
yio gbe agbọn rẹ,
yio ma wa ohun ti o le dimu,
yio si ma na ika ẹsẹ rẹ.
|
Capítulo 33 Fusão da Pálpebra
|
| |
| Laarin ọsẹ keje si ikẹjọ,
ipenpeju oke ati isalẹ
yio bo oju ọmọ inu oyun naa,
yio si so pọ ni ẹgbẹ kan.
|
Capítulo 34 Movimento de Respiração e Micção
|
| |
| Biotilẹjẹpe ko si atẹgun
ninu apo ile-ọmọ,
ọmọ inu oyun naa
yio ti bẹrẹ sii mi lati ọsẹ kẹjọ.
|
| Ni asiko yi, kidinrin rẹ yio ti maa mu itọ jade
sinu omi ti o wa ninu apo ile-ọmọ.
Ni ara ọmọ inu oyun ti o jẹ ọkunrin,
koro ẹpọn ti ndagba lara rẹ yio
bẹrẹ si mu ohun ti a npe ni tẹsitositẹrooni jade.
|
Capítulo 35 8 a 9 Meses (32 a 36 Semanas): Formação dos Alvéolos, Segurar com Força, Preferências de Gosto
|
| |
| Awọn egungun ara, orike ara, ẹran ara, isan ara,
ati awọn ẹya ara ti ẹjẹ ngba san kaakiri,
eyiti o wa ni ọwọ ati ẹsẹ
fi ara jọ ti agbalagba.
Ni ọsẹ kẹjọ, awọ ara
yio bẹrẹ si nipọn sii,
ki yio si mọ gaara mọ.
Irun yio hu si oke oju ati ayika ẹnu.
|
Capítulo 36 Resumo das Primeiras 8 Semanas
|
| |
| Ọsẹ kẹjọ ni opin akoko ẹmubirayoo.
Ni asiko yi,ọmọ inu oyun naa
ti dagbasoke lati ẹyin kekere kanS̩oS̩o
si ọkẹ aimọye ẹyin keekeke,
eyiti yio di awọn orisirisi ẹya ara
miran ti o le ni ẹgbẹrun mẹrin.
Ọmọ inu oyun naa ni
ida aadọrun ninu ọgọrun
ẹya ara agbalagba enia.
|